Ọgọ́rùn ún Ènìyàn Ti Gbèkuru Jẹ Lọ́wọ́ Ẹbọra Nínú Ìṣẹ̀lẹ̀ Àdó Olóró Tó Bú Gbámù Ní Mọ́sálásí Kan Ní Pakistan
Ọgọrùn Ènìyàn ló ti gbẹ̀mí mì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù àti ìgbẹ̀mí ara ẹni pẹ̀lú àdó olóró ní Mọ́sálásí kan ní Pakistan láti ọwọ́ àwọn adìhámọ́ra ogun.
“Ni báyìí, ọgọ́rùn ùn òkú ènìyàn ni wọ́n ti gbé wá sí ilé ìwòsàn ‘Lady Reading'” , agbẹnusọ ọkùnrin ilé ìwòsàn, Mohammad Asim, ló sọ èyí ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni tí àdó olóró pa ni àwọn ọlọ́pàá”, o sọ èyí bákannáà.
Ìròyìn ròó pé, ó ju àrùn dín lọ́gbọ̀n lé lùgba ènìyàn ló ti kú nínú ìkọ̀lù náà.
Òrùlé Mọ́sálásí tó wà nínú ilé ààbò ti ìjọba ló wó lulẹ̀ nígbà tí àdó olóró ń sọsẹ́, àwọn adóòlà ẹ̀mi nílàti kó àwọn pàntí tó wà lórí àwọn oku ènìyàn kúrò kí wọn tó lè rí wọn fà yọ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ se sọ.
Ìkọlù náà ló lágbára jù ní agbègbè Peshawar láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn nínú ìjà àjàkú akátá pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply