Ikọ̀ Chelsea ti tẹwọ́ bọ Ìwé Àdéhùn pàsépáàrọ̀ pẹ̀lú ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù Benfica’s Enzo Fernandez tó wà ní ikọ̀ Benfica ní iye tí owó rẹ̀ lè ní mẹ́fa lé ní Ọgọrùn ún Mílíọ̀nù Euro.
Fernandez ẹni ọmọ ọdún méjìlelógún tẹwọ́ bọ ìwé àdéhùn ọlọ́dún mẹ́jọ ààbọ̀ pẹlú ìkọ tuntun náà títí di ọdún 2031. Àdéhùn yìí niye lórí ju eléyìí ti ikọ̀ Manchester City fi ra agbábọ̀ọ̀lù
Jack Grealish wá láti ikọ̀ Aston Villa ní iye owó Ọgúrùn ún Mílíọ̀nù Euro ní ọdún 2021.
Ní Sáà yí, Fernandez ti gbá bọ́ọ̀lù mẹ́rin sí àwọ̀n, ó se ìrànwọ́ ní ìgbà méje, nínú ìdíje mọ́kànlélọ́gbọ̀n tó ti kópa fún ìkọ Benfica. Fernandez se bẹbẹ ní ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó kọjá lọ. Ó gba àmì ẹ̀yẹ ọmọdé agbábọ́ọ̀lù tó kéré jù ni ìdíje náà,
O tún ran ikọ̀ Argentina lọ́wọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní ọdún tó kọjá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
.
Leave a Reply