Ààrẹ Buhari ti fi àrídájú hàn pé ètò owó tuntun kò ní kó ìpalára bá ọrọ̀ ajé àti ìgbáyégbádùn mùtúmùwà.
Ó sọ ọ̀rọ̀ náà láti le è tu àwọn ènìyàn nínú látàrí wàhálà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira tí wọ́n ń kojú lásìkò ìpààrọ̀ owó. Àrẹ sàlàyé pé, ètò náà wà fún gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́, ìgbésùmọ̀mí, àti ìkówópamọ́ lọ́nà àìtọ́, kìí ṣe ọ̀nà láti mú ìnira bá mẹ̀kúnnù àtipé ètò náà yóò mú ọrọ̀ ajé dúró sinsin.
Ààrẹ fi àrídájú hàn pé ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ti setán láti kó owó tuntun jáde lọ́pọ̀ yanturu.
Leave a Reply