Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pè fún àlékún ìsúná owó sí ẹka ìlera lójúnà àti pèsè ètò ìlera tí ó dára ní orílẹ̀ èdè wa.
Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Dókítà Innocent Orji fi ọ̀rọ̀ léde ní ìparí ìpàdé ọlọ́jọ́ mẹ́ta tí àwọn olóyè àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà se ní ìlú Uyo ní ọjọ́ Àbámẹ́ta (Saturday) tí àkọmọ̀nà rẹ̀ jẹ́ “ Mímú Àlékún Bá Ìgbáyégbádùn àwọn Òṣìsẹ́ Ètò Ìlera”.
Ẹgbẹ́ náà wá rọ ìjọba àpapọ̀ láti gba àwọn òṣìsẹ́ elétò ìlera fún dídí àyè tí ó sófo àti mímú àlékún bà ètò ìsúná ẹka ìlera.
Leave a Reply