Take a fresh look at your lifestyle.

A Kò Sàtìlẹyìn Kíkó Ohun Ìjà Fún Russia- Orílẹ̀ Èdè North Korea Fi Ọ̀rọ̀ Léde

0 256

Orílẹ̀ èdè North Korea ti sọ wípé òun kò kópa nínúu ṣíṣe àtìlẹyìn nǹkan ogun fún orílẹ̀ èdè Russia,  Ó sọ eléyìí lójúnà àti se àfọ̀mọ́ ẹ̀sùn tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fi kàn-án.

 

Ọ̀gá àgbà kan ní orílẹ̀ èdè North Korea sàlàyé ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Àìkú (Sunday) nígbà tí ó sọ pé ẹ̀sùn náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àtipé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fẹ́ sègbè fún ara rẹ̀ ni.

 

Alákòsóo àgbà ti orílẹ̀ èdè North Korea, Kwon Jong Gun rí ẹ̀sùn náà bíi èyítí ó burú púpọ̀, Ó wá kìlọ̀ pé kí orílẹ̀ èdè Améríkà jáwọ́ nínú irúfẹ́ ìfẹ̀sùnkàn bẹ́ẹ̀ kí ó má baà kábàmọ́ọ̀ lẹ́yìn ọ̀rọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button