Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Da Ẹ̀bẹ̀ Siasia Nù Bí Omi Ìṣanwọ́

0 243

 

Ilé ẹjọ́ ní New York ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ẹjọ́ ògbéni Samson Siasia, akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí, ti da ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ láti lè máa tẹ̀ siwaju bi akọ́nimọ̀ọ́gbá nù bí omi ìṣanwọ́.

 

Níbi ìdájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí wọ́n se ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ni wọ́n ti sọ pé àwáwí rẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀.

 

Ní ọdún 2019, àjọ FIFA gbé ote ayérayé lórí Siasia látàrí ẹ̀sùn owó Kọ́bẹ́ ti wọ́n sọ pé ó gbà fún ìdíje bọ́ọ̀lu Orílẹ̀-èdè Australia. Òté náà kò fún láàyè láti lo ìwé ẹ̀rí ti akọ́nimọ̀ọ́gbá rẹ̀ ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

 

Siasia, olúgbe Atlanta agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbé àjọ FIFA lọ ilé ẹjọ́ ní oṣù kejo ọdún 2021, wí pé ìyá náà ti pọ̀jù fún òun àti pé ó tako ànfààní tí òun ní lábẹ́ òfin Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gege bi ẹ̀ni tó ni ìwé ẹ̀rí tó yanrantí bí akọ́nimọ̀ọ́gbá.

 

Agbejọ́rò Siasia, Nitor Egbarin sọ wí pe ìdájọ́ náà leè jẹ́ òpin àwíjàre ọ̀gbẹ́ni Siasia, sùgbọ́n òun pẹlú rẹ̀ á sì tún sọ̀rọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tó kàn.

 

Àjọ ere bọ́ọ̀lu àgbáyé tí olú ìlú rẹ̀ wà ní
Zurich, Orílẹ̀-èdè Switzerland ló fi òfin de ògbẹ́ni Siasia lábẹ́ òfin ti Swiss.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button