Ààrẹ Muhammadu Buhari tí dé sí Dakar, Olú-ìlú Senegal, lori àpéjọ ẹlẹẹkeji irú rẹ̀, tí “Dakar International Conference on Agriculture.”
Ààrẹ Buhari ló fí ìlú Èkó sílẹ̀ lọ́ sí orílẹ̀-èdè Senegal lọ́jọ́ Ìṣẹgun lẹ́yìn àbẹ̀wò oníṣẹ́ ọlọ́jọ́ méjì sí Ìpínlẹ̀ náà níbi tó ti ṣí ìfilọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè kàn bíi: Lekki Deep Sea Port àtí Imota Rice Mill èyí tí wọ́n ró pé yóò pèsè ìṣẹ́ tí ó tó ọ̀ọ́dúrún (300,000) fún àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ náà àti Orílẹ̀-èdè lápápọ̀.
Ààrẹ Senegal tó tún jẹ́ Alága tí Ìsọkan Áfríkà (African Union) ní ó pé àpéjọ náà tó dá lórí “Ìpèsè Oúnjẹ nílẹ̀ Adúláwọ̀: Àgbàrá Oúnjẹ àti Ìfọkànsí (Feeding Africa: Food Sovereignty and Resilience)”
Àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà ní Orílẹ̀-èdè Senegal àtí Bánkì Ìdàgbàsókè nílé Áfríkà (Africa Development Bank) ṣé agbatẹru rẹ̀.
Ó dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀wá àwọn àlejò tí wọ́n ń retí, lára wọ́n ní àwọn Ààrẹ àtí Alàkóso àwọn orílẹ̀-èdè, Mínísítà ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣúná gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn Mínísítà ètò ọ̀gbìn, àwọn Gómìnà Bánkì Orílẹ̀-èdè kọ̀ọ́kàn, àwọn aládàání, àwọn ọmọwè àtí àwọn onímọ̀ ìjìnlè.
Lekan Orenuga
Leave a Reply