Ikọ̀ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ẹka Hadin Kai ti sekú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alákatakítí ikọ̀ Boko Haram ní òpópónà Damboa sí Maiduguri ní ìpínlẹ̀ Borno.
Ìgbésẹ̀ náà wà ní ìbamu pẹ̀lú ìpinnu láti pinwọ́ iṣẹ́ láabi àwọn ikọ̀ burúkú náà ní àgbègbè Borno.
Ohun ìjà olóró bíi MRAP, Alùpùpù, àti àwọn ohun ìtọ́jú àìlera ni àwọn ọmọ ogun gbà lọ́wọ́ ọ wọn.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà rere fún àdúrà àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ fún àseyọrí wọn.