Ilé ẹjọ́ gíga orílẹ̀ èdè Rwanda ti ju mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fún orílẹ̀ èdè náà tí ó wà fún Àṣà àti Àmójútó àwọn Ọ̀dọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún látàrí ìwà àjẹbánu.
Ìròyìn fi yéwa pé, wọ́n dá Edouard Bamporiki dúró lẹ́nu iṣẹ́ nínú osù kaàrún ọdún tí ó kọjá, wọ́n sì fi sí àhámọ́ nínú ilé láti le è ṣe ìwádìí tí ó peregedé látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Bamporiki jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, Ó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ààrẹ Paul Kagame, ṣùgbọ́n nínú osù kẹẹ̀sán ọdún tí ó kọjá, ilé ẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n fún un léyìí tí kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Ní ọjọ́ Ajé ni adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Kigali dá ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún fun, kí ó le è jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti se sọ.
[…] Tún kà nípa: Mínísítà Orílẹ̀ Èdè Rwanda Tẹ́lẹ̀ Rí Fi Ẹ̀wọ̀n Jura Látàrí Ìw… […]
[…] Tún kà nípa: Mínísítà Orílẹ̀ Èdè Rwanda Tẹ́lẹ̀ Rí Fi Ẹ̀wọ̀n Jura Látàrí Ìw… […]