Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó pè fún sísọ àwọn ilé ìwòsàn gbogboogbò kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó di onípele gíga

0 206

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti pe fun sisọ awọn ile iwosan gbogboogbo kan ni Ipinlẹ Eko di onipele giga fun awọn itọju pataki kan. Awọn ile-iwosan naa ni wọn mu kaakiri ẹkun maraarun ipinlẹ yii.

Awọn ile-iwosan gbogboogbo ti yoo di onipele giga naa ni Ile-iwosan gbogboogbo ilu Badagry, ti ilu Ikorodu, ti agbegbe Alimọṣọ, ti ilu Ẹpẹ ati Erekusu Eko.

Ile Aṣofin naa fi ipinnu naa lelẹ lẹyin ayẹwo finnifinni ti wọn ṣe fun abajade iwadii Igbimọ to n mojuto ọrọ Ilera ninu Ile Igbimọ Aṣofin naa, eyi ti Alaga Igbimọ naa, Aṣofin Oluṣọla Ṣokunle jabọ.

Ninu abajade naa ni Aṣofin Ṣokunle ti sọ pe sisọ awọn ile-iwosan yii di onipele giga yoo le mu adinku ba bi ọpọ awọn alaisan ṣe n ṣamulo Ile-iwosan onipele giga kan ṣoṣo ti o wa ni Ipinlẹ yii, iyẹn Ile-iwosan Akọṣẹmọṣẹ Fafiti Eko ni Ikeja, iyẹn ‘LASUTH’, nigba ti o pe fun pipese awọn ẹka itọju aisan kidinrin ati arun rọnilapa-rọnilẹsẹ si awọn ile-iwosan ti wọn ba sọ di onipele giga yii.

Alaga igbimọ yii tun pe fun ṣiṣe atunṣe si awọn ile-iwosan kereje-kereje to wa kaakiri ilu, ki awọn ijọba ibilẹ si maa polongo fun awọn ara ilu lati maa lo awọn ile iwosan kereje yii deedee.

Alaga naa tun fi kun ọrọ rẹ pe, awọn amuyẹ ti awọn fi mu awọn ile-iwosan gbogboogbo ti wọn yoo gbe ga marun-un yii ni, bi wọn ṣe ni irin-iṣẹ iṣetọju si, bi awọn oṣiṣẹ olutọju to wa nibẹ ṣe dantọ si ati bi wọn ṣe ni aaye to lati gba awọn nnkan idagbasoke miiran si.

Ninu iwoye tirẹ, Aṣofin Wahab Jimoh to n ṣoju ẹkun idibo Apapa keji sọ pe, dipo ti wọn yoo tun fi maa ṣafikun ile-iwosan ni Erekusu Eko, ti o ti ni ọpọ awọn ile-iwosan ni ti orilẹ-ede yii ati lati ilẹ okeere tẹlẹ, o yẹ ki wọn mu idagbasoke bẹẹ wa si agbegbe Surulere tabi Mainland.

Aṣofin Mojisọla Meranda, Ọlọpaa ile, sọ pe, yatọ si pipese ẹka Itọju aisan kidinrin ati arun rọnilapa-rọnilẹsẹ si awọn ile-iwosan yii, ẹka itọju awọn alaisan pajawiri ati tito egungun naa ṣe pataki nibẹ, nitori ile-iwosan Gbagada nikan ni wọn maa n gbe awọn onijamba pajawiri bayii lọ.

Aṣofin Moshood Oshun to n ṣoju ẹkun idibo Mainland keji pe fun ṣiṣe idasilẹ awọn ile-iwosan gbogboogbo miiran kaakiri ipinlẹ yii. O ni, dipo sisọ awọn ile-iwosan gbogboogbo marun-un yii di onipele giga, ki wọn ṣe idasilẹ ọpọ ile-iwosan gbogboogbo kaakiri awọn ijọba ibilẹ, ki awọn ara ilu le ni anfani si itọju ni kiakia.

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa sọ pe, a ni lati fi riri awọn ile-iwosan maraarun yii mulẹ nipa sisọ wọn di onipele giga.

Aṣofin Ọbasa sọ pe, o ṣe pataki ki awọn ile-iwosan gbogboogbo wa ni iṣokan, ki wọn si ṣe iwadii onka lawọn ile-iwosan yii lati mọ boya yoo nilo lati ṣe idasilẹ Ile-iwosan pataki fun Itọju aisan kidinrin ati arun rọnilapa-rọnilẹsẹ ni ipinlẹ yii.

Leave A Reply

Your email address will not be published.