Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Àpapọ̀ Sọ Òpópónà Tuntun Di Lílò Fún Mùtúmùwà Ní Ìpínlẹ̀ Plateau

0 170

Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fi òpópónà oní kìlómítà méjì tí ó sẹ̀sẹ̀ parí lé àwọn alákòsóo ilé ìwé gíga Yunifásitì Ìlú Jos, ìpínlẹ̀ Plateau lọ́wọ́ fún lílò.

 

Níbi ayẹyẹ sísí òpópónà náà, Mínísítà fún àkànse iṣẹ́ àti ilé kíkọ́, Babatunde Fashọla sọ pé, irú àkànse iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú ètò ìwé kíkà rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti fún ìgbáyégbádùn wọn.

 

Adarí ilé ẹ̀kọ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tanko Ishaya dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ fún àtúnṣe òpópónà náà.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.