Take a fresh look at your lifestyle.

Àgbéga Dé Bá Ilé Ìwòsàn Àpapọ̀ Márùn-ún Ní Ìpínlẹ̀ Èkó

0 136

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ti pèpè fún mímú àgbéga bá ilé ìwòsàn àpapọ̀ márùn-ún ní ìpínlẹ̀ náà.

 

Àwọn ilé ìwòsàn àpapọ̀ náà ni èyí tí ó wà ní Badagry, Alimosho, Ikorodu, Epe àti Lagos Island.

 

Ìgbésẹ̀ akin náà wáyé nígbà tí àwọn ìgbìmọ̀ ní ẹka ètò ìlera ilé ìgbìmọ̀ asòfin se àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwòsàn náà lójúnà àti mọ ipò tí wọ́n wà. Àfẹnukò sì wáyé pé, ó se pàtàkì láti mú àgbéga bá àwọn ilé ìwòsàn náà.

 

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ náà, Mudasiru Obasa sọ pé mímú àgbéga bá àwọn ilé ìwòsàn àpapọ̀ náà se kókó.

Leave A Reply

Your email address will not be published.