Take a fresh look at your lifestyle.

Obìnrin Àkọ́kọ́ Jẹ Oyè Àlùfáà Ní Ilẹ̀ Mímọ

0 124

 

Ní ọjọ Àìkú, ará Palestine ní ìlú Jerusalem, Sally Azar, jẹ oyè Pásítọ̀ ni ilé ìjọsìn Lutheran tó kalẹ̀ sí àárín ilú nla àtijọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn káàkiri ayé sí péjọ fún ayẹyẹ náà.

Àwọn ẹlẹ́sìn krìstìánì kò wọ́pọ̀ ní agbègbè Palestine, Israel, àti Jordan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n jẹ́ ti ìjọ Àgùdà tàbí ti àwọn ìjọ ayé àtijó tí wọ́n kò fàyè gba Obìnrin láti ṣe ìwàásù.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìyànsípò àwọn Obìnrin sí ipò àlùfáà ti wá wọ́pọ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹwàá àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn báyìí. Àwọn ilé ìjósìn kékèké yìí náà ti ń dá ilé ìwé àti ilé ìwòsàn sílẹ̀ ní ilẹ̀ mímọ́

Bàbá rẹ̀, Biṣọ̀ọ̀bu Sani Azar ló fi MS Azar jẹ oyè. Obìnrín náà sọ wípé àpẹẹrẹ rere ti bàbá òun ló se ìwúrí fún òun. Ó sọ wípé ó rọrùn fún òun nígbà tí òun ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gba oyè àlùfáà àti wípé nǹkan tí òun fẹ́ ni, ó sì wù òun.
Àwọn olúlùfẹ́ Rev Azar gbàgbọ́ pé obìnrin náà yóò lè pe ìpèníjà láti yí àwọn ìtàn àtijọ́ nípa ẹ̀sìn padà.

Ní agbègbè Middle East, Ilé ìjósìn ní ìlú
Lebanon àti Syria ti ni Obìnrin ni ipò oyè àlùfáà, ókéré tán Obìnrin ará Palestine kan ló ti di mímọ̀ pé ó dipò àlùfáà mú ní ìlú Améríkà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.