Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ölù Arsenal Fi Àmì Márùn- ún Gédéngbé Lékè Tábìlì Ju Àwọn Ikọ̀ Yóókù Lọ

0 108

 

Àwọ̀n méjì tí agbábọ́ọ̀lù Eddie Nketiah mì tìtì jẹ́ kí ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lu Arsenal fi ayò mẹ́ta sí méjì (3-2) borí ìfdaagagbága pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lu Manchester United. Eléyìí jẹ́ kí wọ́n fi àmì márùn ún tayo gbogbo ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù yókù lórí tábìlì.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United.ló kọ́kọ́ dá àwọ̀n lu láti ẹsẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Rashford ní ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún ti ìdíje bẹ̀rẹ̀. Arsenal sí dáa padà nígbàtí Nketiah fi orí kan bọ́ọ̀lù wọlé.,

Ẹgbẹ́ agbábọ́ölù Arsenal tún rí àwọn míràn he látesẹ̀ Saka ní ìṣẹ́jú mẹ́tàléláàdọ̀ta, tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United tún dá padà nígbàtí ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù nì tó gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé pẹ̀lú ikọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́sí, Lisandro Martinez fi orí gybe bọ́ọ̀lù Wọlé Arsenal ni ayò wá di méjì sí méjì (2-2).

Nketiah ló sọ ẹlẹ́ẹ̀keta ṣí àwọ̀n fún ikọ̀ Arsenal nígbàtí ó ran Martin Odegaard lọ́wọ́ láti darí bọ́ọ̀lù tó gbá dáadáa sínú àwọ̀n ni ayò bá wá di mẹ́ta ṣí méjì (3-2) tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal sì borí.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ölù Arsenal ló wà ní ipò kínní lórí tábìlì, United wa ní ipò kẹ́rin lórí tábìlì, àmì mọ́kànlá sí ẹgbẹ́ agbaboyolu Arsenal.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ölù Arsenal yóò kojú Manchester City ní ọjọ́ Ẹtì fún ìdíje FA Cup ti ipele kẹ́rin, Manchester United ní tirẹ̀ yóò kojú Nottingham Forest ní ìdíje
Carabao Cup abala àkọ́kö ipele tó kángun sí àsekágbá ní ọjọ́ Ọjọ́rú.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.