Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Olùgbé Orílẹ̀-èdè Burkina Faso Ń fẹ́ Kí Ìjọba Ológun Faransé Máa Lọ

0 82

Àwọn ènìyàn ni orile-ede Burkina Faso ti tẹ́wọ́gba èròngbà àwọn ijọba ológun látí lè ìkọ ìjọba àwọn ológun tí Faransé dànù lórí àlééfà ki oṣù kan tó pari.

 

Oníròyìn láti orílẹ̀-èdè wọn lo ròó fáyé gbọ́ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kínní láti lè wọn dànù tèfètèfè ní orílẹ̀-èdè wọn.Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n se ìwọ́de ní olú ìlú wọn – Ouagadougou pé àwọn fẹ́ kí wọ́n máa lo.

Adama Tapsoba sọ wípé, “Wọ́n nílàti lọ, wọ́n nílàti lọ ni, kí wọ́n fi àwọn sílẹ̀ jàre, àlàáfíà ni àwọn ń fẹ́, à ní àlàáfíà nìkan ni.”

 

Ó ju ọgọ́ta ọdún lọ lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Burkina Faso ti gba òmìnira tí orílẹ̀-èdè Faransé ti takú tì wọ́n tí wọn kọ̀ láti lọ, wọ́n ró ọrọ̀ ajé wọn lágbára, wọ́n se ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn, síbẹ̀ ìgbésẹ̀ àwọn Faransé ti ṣú àwọn ènìyàn.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.