Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ̀wé Ilé Ìṣúra Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Yellen Bẹ Orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́ga Wo

0 76

 

Akọ̀wé Ilé Ìṣura Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Janet Yellen bẹ ilé aláwọ̀ píńkìì ní ìkọjá erékùṣù ti Orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́ga Wo.
Ìbẹ̀wò Yellen jẹ́ ara ìbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá pẹ̀lú èròngbà láti tù àjọṣepọ̀ ọrọ̀ ajé tó wà láàárín ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ti Adúláwọ̀ se.
Ilé náà ní a mọ̀ sí ilé òwò ẹrú tí ọ̀kẹ́ àìmọye mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ ti rin ìrìn-àjò àrìnmabọ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi lọ sí òkè òkun.

 

Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ẹrú àti ọmọ wọn kó ipa ribiribi nípa kíkọ́ àwọn ilé alájà gíga bíi White House àti Capitol gẹ́gẹ́ bí ìròyìn àsẹ̀ǹbáyé se sọ.

 

Ìrìn àjò Yellen sí erékùṣù náà jẹ́ ọ̀kan lára irúfẹ́ ìrìn-àjò tí àwọn èèkàn ènìyàn pàtàkì bíi ààrẹ tẹ́lẹ̀ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Barack Obama àti Bill Clinton àti ààrẹ tẹ́lẹ̀ ti ilẹ̀ South Africa, Nelson Mandela ti se.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.