Àjọ ‘Continental Reinsurance Plc’ ti pe àwọn oníròyìn jákèjádò láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ wọn fún idanilola àmì ẹ̀yẹ ti àwọn oníròyìn ti ọdún 2023.
Wọ́n pe ìpè yí láti bù ọlá fún àwọn oníròyìn tó peregedé ní àwùjọ Oníròyìn.
Àjọ náà sọ wípé, ìfi àmì ẹ̀yẹ dánilọ́lá náà ló jẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ irú rẹ̀, wọ́n sì pé gbogbo àwọn Oníròyìn jákèjádò àgbáyé láti fi iṣẹ́ wọn ránṣẹ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé tàbí Lárúbáwá láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kọkànlá ọdún 2022 títí di ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Kejì ọdún 2023.
Àwọn Oníròyìn tó nífẹ̀ẹ́ láti kópa nílàti fi ìwé àti iṣẹ́ wọn ránṣẹ́ sí ọ̀dọ̀ àjọ náà lórí òpó ayélujára wọn.
Ọ̀gbẹni Destiny Onyemihia, láti ilé ìṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Voice of Nigeria jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ ti ẹlẹ́ẹ̀keje irú rẹ̀ ní ọdún tó kọjá gẹ́gẹ́ bí ẹni tó se dáradára jù ní ẹ̀ka oníròyìn ti èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply