Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Yóò Lọ Ṣí Ìlú Dakar Fún Ìpàdé Lórí Ètò Ọ̀gbin

0 76

 

Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò kúrò ní ìlú Èkó lọ sí Orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́gà ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun fún ìpàdé elẹ́kejì irú rẹ̀ ti àgbáyé lórí ètò ọ̀gbìn.

 

Ààrẹ Macky Sall ti ilẹ̀ Sẹ́nẹ́gà tó tún jẹ́ alága àgbáríjọpọ̀ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni yóò gbàwọ́n lálejò. Lórí Àkòrí:
Fífún ilẹ̀ Adúláwọ̀ lóúnjẹ: Agbára oúnjẹ àti Ìpadàbọ̀sípò rẹ̀ 

Ìpàdé náà yóò fi àyè sílẹ̀ fún ìjíròrò lórí ìpèsè oúnjẹ yanturu ní ilẹ̀ adúláwọ̀, ni wọ́n gbékalẹ̀ láti ọwọ́ orílẹ̀-èdè Sẹ́nẹ́gà àti àjọ African Development Bank.

Àyè sì tún má wà fún ìpàdé lórí ètò ìgbọ́raẹ̀niyé oúnjẹ àti ètò ọ̀gbìn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára wọn pẹ̀lú èròngbà láti lè ebi, ìṣẹ àti òsì wo igbó kò tó di ọdún 2030 ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Àwọn tó bá ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí kọ̀wọ́ rìn lati rí Mínísítà fún ọ̀rọ̀ nípa ìlú òkèèrè,
Geoffrey Onyeama,, Mínísítà fún ètò ògbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, Dókítà Mohammad Mahmood Abubakar, Agbani-nímọ̀ràn àpapọ̀ ti ètò ààbò, Mohammed Babagana Monguno, àti Ọ̀gá ti àjọ National Intelligence Agency (NIA), Ahmed Rufa’i Abubakar.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.