Àjọ tó ń rísí ètò ìrìn àjò lọ sílẹ̀ mímọ́ ní Nàìjíríà NAHCON, ti mu dá àwọn arìnrìn àjò lójú pé kò ní sí àìsedéédé kankan nínú ètò ìrìn àjò ọdún 2023.
Eléyìí wà nínú àtẹ̀jáde kan tí igbákejì adarí NAHCON fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àtẹ̀jáde, Alhaji Mousa Ubandawaki,buwọ́lù.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé,àjọ náà ṣe ìdánilójú náà, nígbà tí ikọ̀ aṣojú kan ṣàbẹ̀wò sí olú ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú àpapọ̀ (GACA), ní Jeddah, Saudi Arabia.
Alága àjọ ètò ìrìn àjò mímọ́ náà, Alhaji Zikrullah Hassan, nígbà tí ó ń dúpẹ́ fún àtìlẹyìn GACA, fún ètò ìrìnrìn àjọ̀ ọdún tó kọjá,tún fìdí ìfọkànsí ìgbìmọ̀ náà láti jẹ́ kí ètò tọdún yìí jẹ́ àṣeyọrí múlẹ̀.
Nínú èsì rẹ̀, olùṣàkóso gbogbogbòò ètò ìrìn àjò mímọ́,Onímọ̀ẹ̀rọ Nazim Pazhair, wá gbóríyìn fún NAHCON fún iṣẹ́ ribiribi lórí ipa rẹ̀ fún ìlọsíwájú ìgbé àlààfíà àti ètò ìṣiṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn arìnrìn àjò Nàìjíríà.
Leave a Reply