Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ̀wé ẹgbẹ́ NNPP Àriwá Oòrùn tẹ́lè sún sí ẹgbẹ́ PDP

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 104

Akọ̀wé ẹgbẹ́ New Nigeria People’s Party, NNPP, Àriwá Oòrùn tẹ́lẹ̀, Dókítà Babayo Liman, ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ People’ Democratic Party, PDP.

Nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní Gombe, Dókítà Liman, tí ó jẹ́ alákòóso ìpolongo Àríwá Oòrùn, ikọ̀ Kwankwasiyya fún olùdíje ipò ààrẹ ẹgbẹ́ NNPP tẹ́lẹ̀, Aṣojú ṣòfin Rabiu Musa Kwankwaso, sọ pé tí wọ́n bá yan olùdíje ààrẹ PDP  yóò tún ṣe bẹbẹ tí PDP ti ṣe ní Nàìjíríà fún ọdún mẹ́rìndín-lógún tí ó fi ṣàkóso náà.

Ó sọ pé ọdún mẹ́rìndín-lógún ìṣàkóso ẹgbẹ́ PDP ní Nàìjíríà jẹ́ àṣeyọrí àrà ọ̀tọ̀.

Dókítà Liman wá sọ pé òun ń darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ PDP, nítorí pé òun fẹ́ kín olùdíje ààrẹ PDP, Àtíkù Àbúbákàr lẹ́yìn, tí ó wá rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́  Gombe tí ó ju igbàata lọ láti ṣàtìlẹyìn fún olùdíje ààrẹ PDP, àti àwọn olùdíje PDP jákèjádò orílẹ̀-èdè.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.