Take a fresh look at your lifestyle.

Akọrin Amẹ́ríkà Snoop Dogg fìfẹ́ẹ̀ hàn láti kọrin pẹ̀lú Tems

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 170

Akọrin Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Snoop Dogg ti fihàn gbangba sí Akọrin ìlú mọ̀ọ́ká Nàìjíríà Tems, pé òun fẹ́ kí wọ́n jọ kọrin papọ̀.
Snoop Dogg fi èyí ránsẹ́ sórí ayélujára Instagram Tems, tí Tems náà sì fi fídíò gbajúgbajà Akọrin Amẹ́ríkà náà síta,nínú èyí tí ó ti ń sọ pé òun nífẹ̀é sí orin Tems àti bí òun yóò ṣe fẹ́ kí àwọn jìjọ kọrin papọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Snoop Dogg,ó ní àwọn ẹbí òun máa ń gbádùn orin Tems,òun yóò sì fẹ́ kí àwọn jọ kọrin papọ̀.

Tems wáá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ látoríi ayélujára Twitter rẹ̀,tí inú rẹ̀ sì dùn pé gbajúgbajà akọrin ríran rí òun nítorí pé ,òun náà jẹ́ gbajúgbajà.

Leave A Reply

Your email address will not be published.