Take a fresh look at your lifestyle.

2023 :Olùdíje ipò gómìnà fún ẹgbẹ́ NNPP, ní Násáráwá tẹramọ́ ìpolongo ní ìgbèríko

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 105

Olùdíje gómìnà fún ẹgbẹ́ New Nigeria People Party (NNPP),Ọ̀gbẹ́ni Abdullahi Maidoya ti túnbọ̀ tẹramọ́ àkójọpọ̀ fún ìpolongo ní agbègbè iwọ̀ oòrùn, ní ìpínlẹ̀ náà.

Maidoya sọ pé àkójọ fún ìpolongo ẹgbẹ́ ní àwọn ìgbèríko jẹ́ ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ láti ṣàṣeyọrí lórí ìbò gbogbogbòò oṣù tó ń bọ̀.

Nígbà tí ó ń bá àwọn ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ní agbègbè ìdàgbàsókè Umaisha, ti ìjọba ìbílẹ̀ Toto, ní ìpínlẹ̀ náà. Abdullahi Maidoya pinnu pé òun yóò pèsè ìtọ́jú aláboyún lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn obìnrin, àti ètò ẹ̀kọ́ tí kò gara lọ,tí wọ́n bá dìbò yan òun.

Ó tún wá ń fi dá àwọn agbègbè náà lójú pé òun yóò kọ́ ilé-ìwòsàn gbogbogbòò jákèjádò ìpínlẹ̀ láti pèsè ètò ìlera tó múnádóko.

Ó wá ṣe ìlérí láti fi òpin sí ìtaláyà ààbò nípa fífi àwọn àgbẹ̀ àti àwọn adaran sáyè oníkálukú jákèjádò ìpínlẹ̀ fún ìdàgbàsókè.

Leave A Reply

Your email address will not be published.