Take a fresh look at your lifestyle.

2023: Olùdíje ipò ààrẹ PDP Pinnu láti parí èbúté ìpínlẹ̀ Niger

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 127

Olùdíje ipò ààrẹ fún egbẹ́ People’s Democratic Party ní Nàìjíríà PDP, Alhaji Àtíkù Àbúbákàr, ti pinnu láti ṣe iṣẹ́ àkànṣe Baro Baro parí tí wọ́n bá dìbò yan òun nínú ìdìbò gbogbogbòò yìi.

Alhaji Àtíkù Àbúbákàr sọ èyí lásìkò àpèjọ fún ìpolongo ní ìpínlẹ̀ Niger, Àriwá Àringbùngbùn Nàìjíríà.

Olùdíje ààrẹ ẹgbẹ́ PDP wá fi ẹ̀sùn kàn pé iṣẹ́ àkànṣe èbúté Baro, oní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bílíọ́nù tí ìṣàkóso PDP bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́yìn, kò parí lọ́wọ́ ìṣàkóso ẹgbẹ́ APC lẹ́yin tí ẹgbẹ́ PDP gbé ìjọba sílẹ̀, lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ.

Àtíkù wá túnbọ̀ rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti dìbò yan òun àti gbogbo àwọn olùdíje  PDP, ó sọ pé kí wọ́n máá ṣiyè méjì lórí àtìlẹ́yìn àti ìfọkàn tán wọn sí ẹgbẹ́ náà.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.