Àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹ́to aláàbò ni orílẹ̀-èdè Burkina Faso ti gbà awọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tó tó mẹ́rìndínláàdọ́rin sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọn ti wa ni àhámọ́ awọn ajínigbé.
Àwọn Òṣìṣẹ́ Aláàbó yìí rí àwọn tí wọn Jígbé yìí nínú ọkọ̀ nígbà tí wọn lọ fún ayẹwo òpópónà kan
Ìròyìn sọ wí pé ọjọ́ méjì ọ tọ tọ ni àwọn oníṣe Laabi yìí fi ṣiṣẹ laabi won náà , ọjọ́ Kejìlá oṣù kínní àti ọjọ́ kẹtàlá rẹ.
Wọn ti gbà ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ kẹjọ gbákó tí wọ́n ti lo lọ́wọ́ àwon ajinigbe.