Take a fresh look at your lifestyle.

U17 AFCON: Ugbade Pé Àgbábọ́ọ̀lù Méjì-Dín-Làádọ́ta Sí Ìbùdó

0 141

Àkọ́nì-mọ́ọ̀gbà fún ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tí ọjọ́ orí wọ́n kọjá ọdún mẹ́tà-dín-lógún lọ́ (Nigeria U-17), Nduka Ugbade, tí pé àwọn àgbábọ́ọ̀lù mejidinlaadọta sí ibùdó ní Abùjá ní igbaradi fún ìdíje àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n kọjá ọdún mẹ́tà-dín-lógún lọ́ nílẹ̀ Áfríkà (U-17 Africa) tí ọdún yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kàn tí ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù tí Nigeria Football Federation NFF ní Ọjọ́bọ̀ ní pé, àwọn ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù náà yóò bẹ̀rẹ̀ igbaradi wọ́n ní ọjọ́ Àjé bí àwọn àgbábọ́ọ̀lù tí a pé tí gbọ́dọ̀ wà ní ibùdó ní ọjọ́ Ẹtì, ogún ọjọ́, Oṣù Kíní.

Ìdíje U17 náà yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Algeria, látí 8th – 30th Oṣù Kẹrin, ìkọ mẹ́rìn tó bá peregede sí ìpele aṣe kagba ní yóò ṣoju Áfíríkà níbí ìdíje ìfé Àgbáyé FIFA U17 tí orílẹ̀-èdè Peru máa gbalejo rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá Oṣù kọkànlá sí ọjọ́ Kejì Oṣù Kejìlá ọdún yìí.

Tún kà nípa: Ètò Ti Parí Fún Ìfaga-Gbága Ọlọ́rẹ̀ẹ́-Sọ́rẹ̀ẹ́ Láàrin Agbábọ́ọ̀lù Ilẹ̀ Nàìjíríà Àti Zambia

Nàìjíríà ló tí gbà ìfé Àgbáyé FIFA U17 náà ní ìgbà márùn ùn ọtọtọ níbí tí wọ́n ti jáwé olubori ní China ní 1985, Japan ní 1993, Korea Republic ní 2007, United Arab Emirates ní 2013 àti Chile ní ọdún 2015.

Àwọn àgbábọ́ọ̀lù tí wọ́n fí ìwé pé náà níyì:

Richard Odoh, Hameed Ayomide Balogun, Ebube Wisdom Okere, Umar Abubakar, Tochukwu Simeon Ogbabido, Tochukwu Joseph Ogboji, Utibe Friday Silas, Emmanuel Osaro Onotu, Jubril Odeyemi Azeez, Faruq Jimoh, Kevwe Onomigho Iyede, Suleiman Shehu, Abdullahi Buhari, Victor Divine Emmanuel, Daniel Ayomide Egunshola, Abubakar Shuaibu, Ozor Victor Okeke, Emmanuel Michael, Miracle Jackson Ogwor, Light Chijioke Eke, Raphael Oyebanjo, Miracle Agabi Williams, Yahaya Danjuma Lawali, Prince Oche Bawa, Favour Oluwasegun Daniel, Precious Tonye Williams, Jerry Patrick Ogbole, Emmanuel Junior Chidi, Mubarak Emmanuel Suleiman, Abubakar Ibrahim Zubairu, Richard Oliseamaka Uche, Joseph Oluwatobi Robert, Michael Uche Ogba, John Auta, Shola Oluwafemi Kolo, Pascal Obioma Uzoho, Victor Friday, Itaribo Ayebaekepriye, Jeremiah Oluwaseyi Olaleke, Basil Chimaobi Mbata, Oluwadare Olodan, Precious Benjamin, Tochukwu Michael Agbo, Samuel Aderibigbe, Abubakar Idris Abdullahi, Umar Jamiu, Tijjani Mohammed, Abdullahi Haruna

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.