Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Èkó Ṣègbékalẹ̀ Ètò Ìmúgbòòrò Sí Àwọn Ilé Ìtọjú Ìlera Alàkọ́bẹ̀rẹ̀

1 165

Ìgbìmọ̀ Ìtọjú Ìlera àkọ́kọ́ tí ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State Primary Health Care Board LSPHCB) tí ṣé ìfilọ́lẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn ilé-iṣẹ́ Ìlera alakọbẹrẹ ogún (20) (Primary Healthcare Center PHCs) ní àwọn ìpín márùn ùn tí ìpínlẹ̀ Èkó láti mú àwọn iṣẹ́ ìlera náà dára síi.

Akọ̀wé àgbà ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tí ilé iṣẹ́ náà LSPHCB, Dókítà Ibrahim Mustafa, sọ èyí nínú ọrọ̀ kàn tí aṣojú rẹ̀ Filade Olumide, Ìgbákejì Olùdarí ọrọ̀ àwùjọ, ní Ọjọ́bọ̀ ní Èkó. Mustafa ṣàlàyé pé ìgbésẹ náà wà látí mú ìlérí ìjọba ṣẹ́ lórí ìlọsíwájú òún amayedẹrun nínú ètò “THEMES” èyí tí o dúró fún ìlera àti àgbègbè. O fí kún ùn pé ìdàgbàsókè náà ní yóò bẹ̀rẹ̀ ní Mende, Akoka àtí Abule-Nla Healthcare Centres, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Lagos State Infrastructure Management Agency (LASIAMA) àti àwọn oríṣiríṣi àwọn àgbègbè ìjọba ìbílẹ̀.

Tún kà nípa: Ààrẹ Buhari Yóò Ṣé Ìfilọ́lẹ̀ Àwọn Ìṣẹ́ Àkànṣe Ní Ìpínlẹ̀ Èkó

Gẹ́gẹ́ bí bi o ti sọ, ìdàgbàsókè náà yóò pèsè àgbègbè tó dára fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àti àwọn aláìsàn, àtí látí mú ìlọsíwájú bá iṣẹ́ ìlera sí ní àwọn àgbègbè káàkiri ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn Alága ìbílẹ̀ àwọn àgbègbè ogún tí iṣẹ́ àkànṣe náà yóò tí wáyé, ṣé àdéhùn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọ́n àti látí jẹ́ kí ìṣàkóso ìjọba ìpínlẹ̀ náà dára síi.

Lekan Orenuga

1 Comment
  1. Lekan Orenuga says

    Ẹ jọwọ, ẹ jẹ́ kó dé Ìkòròdú o, Ọgá Sanwo-Olu!

Leave A Reply

Your email address will not be published.