Take a fresh look at your lifestyle.

Iná Bẹ̀sílẹ̀ Ní South Korea, Sọ́ Ọ̀ọ́dẹ́gbẹ̀ta Ènìyàn Dì Aláìnílélórí Ní Guryong

0 297

Ó fẹ́rẹ̀ tó Ọ̀ọ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àwọn ènìyàn ní a yọ̀ kúrò ní ilé wọ́n ní ọjọ́ Ẹtì lẹyìn tí ìnà ṣẹ̀lẹ̀ ní abúlé Guryong.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣé sọ, kò tíì sí ẹní tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ní ẹnikẹni kò fí àrà pàá. Fanran kàn lórí ayélujára fihàn pé iná náà jó òpọ̀lọpọ̀ ilé pèlú àwon èéfín iná ṣé bôlẹ̀. Ẹ̀gbẹ́rìn àwọn òṣìṣẹ́ pajawiri ló tí wá nílẹ̀ látí ṣé ìrànlọ́wọ́ fún àwọn olùgbé náà. Díẹ̀ nínù wọ́n ní a tí rí òṣìṣẹ́ oníjà iná, agbofinro àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mìíràn bẹ́ẹ̀ ní bàálù kékeré mẹwàá ń fo lórí òfurufú fún ìrànwọ́ bákannáà, Shin Yong-ho, òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ iná Gangnam (Gangnam Fire Station) sọ́.

Ààrẹ South Korea Yoon Suk Yeol, tó wà ní Switzerland níbí àpéjọ Ìṣòwò Àgbáyé, ní wọ́n tí fí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó létí, ló tí pàṣẹ ìrànwọ́ látí ọdọ gbogbo àwọn élétó ààbò nì ìbámu sí ilé iṣẹ́ Ààrẹ

Yoon tún rọ̀ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ kọ̀ọ́kàn látí ríi dájú pé wọ́n kó àwọn olùgbé náà kúrò àtí ríi dájú pé wọ́n pèsè ààbò tó dájú fún àwọn òṣìṣẹ́ ìgbàlà náà, ọfiisi rẹ sọ.

Àwọn aláṣẹ tí kílọ fún àwọn olùgbé Guryong lori èwù tó wà lórí ibùgbé wọ́n pàtàkì jùlọ àjálù pẹ̀lú èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Gangnam tí sọ lórí òpó ayélujára rẹ̀ ní ọdún 2019 nípa èwù iná.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button