Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Fagilé Ìpẹ̀jọ́ Tí Ó Tako Ààrẹ Buhari

0 102

Adájọ́ Inyang Ekwo ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti da ẹjọ́ tí ó tako ìyànsípò tí ààrẹ Buhari ṣe sí àjọ tí ó ń rí sí àgbègbè (Niger Delta) nu.

 

Onísòwò ńlá kan tí ó fi ìlú Abuja se ibùgbé, Olóyè Arábìnrin Rita Lori Ogbebor ni ó pe ẹjọ́ náà tako Ààrẹ, tí ilé ẹjọ́ sì fi ọwọ́ òsì dàá nù nítorí pé olùpẹ̀jọ́ náà kò ní àṣẹ lábẹ́ òfin láti pe irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.

 

Ẹ̀wẹ̀, olùpẹ̀jọ́ náà fi àìdùnnú rẹ hàn sí ìdájọ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti subú yakata, Ó sì pinnu láti gba ìdájọ́ mínràn ní ilé ẹjọ́ àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.

Leave A Reply

Your email address will not be published.