Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ti Parí Fún Ìfaga-Gbága Ọlọ́rẹ̀ẹ́-Sọ́rẹ̀ẹ́ Láàrin Agbábọ́ọ̀lù Ilẹ̀ Nàìjíríà Àti Zambia

2 212

Agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà U-20 AFCON ti setán láti kojú ojúgbà rẹ̀ ti orílẹ̀ èdè Zambia fún eré ìdárayá ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́. Èyí yóò wáyé ní ìlú Abuja ní ìgbáradì fún àmì ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ ti ọdún yìí.

 

Ikọ̀ méjéèjì ti gbáradì fún eré ìdárayá náà, lẹ́yìn ìgbà tí ikọ̀ Nàìjíríà ti kọ̀wé ráńsẹ́ ní ọjọ́ kẹtàlá osù kíní, tí ikọ̀ Zambia sì fi ọwọ́ síi bẹ́ẹ̀.

 

Eré ìdárayá náà yóò wáyé ní ọjọ́ Ẹtì (Friday) ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n osù kíní àti ọjọ́ Ajé (Monday) ọgbọ̀n ọjọ́ osù kíní.

2 responses to “Ètò Ti Parí Fún Ìfaga-Gbága Ọlọ́rẹ̀ẹ́-Sọ́rẹ̀ẹ́ Láàrin Agbábọ́ọ̀lù Ilẹ̀ Nàìjíríà Àti Zambia”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button