Take a fresh look at your lifestyle.

NGF, Àwọn Kọmisọna Ìlera Gbá Àwọn Ọ̀nà Ọtún Látí Mú Àwọn Ilé ìṣẹ́ Ìlera Dára Sì

0 153

Àjọ Àwọn Gómìnà Nàìjíríà (NGF) àtí àwọn Kọmisọna Ìpínlẹ̀ fún ìlera tí tẹnumọ ìwúlò fún àtúnyẹwò gbogbo ìgbà àti gbígbà àwọn ọnà ọtún ṣé ìṣẹ́ látí ríi dájú àtí ṣé àtúnṣe ìlera gbogbogbò (Universal Health Coverage UHC), pàápàá jùlọ ní awọn àgbègbè ìdàgbàsókè àti ìgbèríko.

Alága, Àjọ àwọn Kọmisọna Ìlera ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yìí (Nigeria Commissioners of Health Forum), Dókítà Oyebanji Filani, tó sọrọ níbí àpéjọpọ̀ àwọn Kọmisọna àtí àwọn alẹnu-lọ̀rọ̀ lórí ìjẹ́ olórí àti ètò ìlera tó yanranti ní Abùjá, ó tẹnumọ ìwúlò fún àwọn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nigba-gbogbo àtí àtúnyẹwò àwọn ọnà látí ríi dájú pé àbájáde náà ní àṣeyọrí.

Dókítà Filani, sọ pé òún pàtàkì tí àwọn olúkópa yóò mú kúrò níbi àpéjọ yìí ní látí ṣé àkójọ pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ pàtàkì àtí amugba lẹgbẹ wọ́n láti lè ràn ètò ìlera àwọn àrà ìlú lọ́wọ́.

Olùdarí Gbogbogbò NGF, Asishana Okauru, nínú àwọn ọrọ̀ rẹ̀, ṣé àpèjúwe àpéjọ náà gẹ́gẹ́ bí òún tó dára nítorí pé èyí ní ìgbà àkọ́kọ́ tí gbogbo àwọn alẹnu-lọ̀rọ̀ ní ẹ̀kà ìlera Orílẹ̀-èdè yìí yóò jókòó pọ̀ jíròrò lórí ìlọsíwájú ètò ìlera àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí.

Nibayii, àwọn Kọmisọna tí ìlera látí àwọn ìpínlẹ̀ Borno àtí Kano, nínú àwọn ọrọ wọ́n, yìn Àjọ NGF fún àtìlẹ́yìn àpéjọ, wọ́n sì ṣé ìdánilójú pé ìmọ àti ẹkọ tí wọ́n kọ́ níbí àpéjọ náà ní wọ́n yóò mulo daradara lójú ọnà ìlera.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.