Take a fresh look at your lifestyle.

Olùkọ́ Àgbà Kan Pè Fún Fífi Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Àyíká Sínú Ètò Ìkọ́ni

0 188

Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹka ìmọ̀ àyíká, ti ilé ìwe gíga Yunifásitì Ìlú Ilọrin, ààrin gbìngbìn Arewa Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abdulraheem Yusuf sọ wípé, fún orílẹ̀ èdè wa láti yege, ìmọ̀ nípa àyíká ṣe pàtàkì ní ẹka ètò ẹ̀kọ́ gbogbo.

 

Ọ̀jọ̀gbọ́n Yusuf fi ọ̀rọ̀ náà léde níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ti ilé ìwe gíga náà pẹ̀lú àkọmọ̀nà “Líla Àwọn Ènìyàn Lójú Fún Ìdóòlà Orílẹ̀ èdè”.

 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, kíkọ́ ìmọ̀ nípa àyíká àti ìbágbépọ̀ jẹ́ ọ̀nà kan gbógì láti tán ìsòro tí ó n kojú orílẹ̀ èdè wa nípa ètò òsèlú àti ọrọ̀ ajé.

 

Ọ̀jọ̀gbọ́n náà wa dábàá pé, kíkọ́ ìmọ̀ nípa àyíká gbọdọ̀ padà sínú ètò ẹ̀kọ́ ní gbogbo ẹka fún àgbọ́yé àti ìbágbépọ̀ àlááfíà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button