Àjọ Kano state Agro Pastoral Project, KSADP, ti fún olùgbé ìpínlẹ̀ kano ní Síkọ́láshìpù tí iye rẹ̀ tó Mílíọ̀nù lọnà ọgọ́fà ó lé mẹ́jọ, àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba o lé àádọta Náírà, gẹ́gẹ́ bí Alàkóso àjọ, ọ̀gbéni Ibrahim Garba ní ìpínlè náà se sọ .
Síkọ́láshìpù náà wà fun akẹ́ẹ̀kọ́ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nipa ìmúgbòrò ètò àgbẹ̀ àti ẹranko.Wọ́n sì ti ṣètò bí àjọ International Institute for Tropical Agriculture(IITA) yóò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ bákannáà.
Ó sọ síwájú pé akẹ́ẹ̀kọ́ Márùndínlọ́gọ́fà náà ni wọ́n fàyọ jáde ninyu ẹgbẹ̀rún ó lé díèẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fi ìfẹ́ wọn hàn látì kópa.Owó ilé ìwé sí wà lára Síkọ́láshìpù náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san