Take a fresh look at your lifestyle.

2023 U20 AFCON: Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles Yóò Ní Ìpàgọ́ Ìgbáradì Ní Òkè-òkun Ní Oṣù Kínní

1 196

 

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles yóò ni Ipagọ́ Ìgbáradì ní Òkè-òkun bẹ̀rẹ̀ ní ìparí oṣù kínní ọdún yìí látàrí ìdíje 2023 U20 AFCON.

 

Eléyìí di mímọ̀ láti ẹnu akọ́ni-mọ̀ọ́gbá wọn- Ladan Bosso. Ó sọ wípé NFF fẹ́ ní ìpàgọ́ fún ẹgbẹ́ ọmọ agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles ni orilẹ-èdè Spain tàbí Morocco.

” A má fi orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí sílẹ̀ ní òpin oṣù láti lọ sí ìpàgọ́ Ìgbáradì wa, “ Bosso sọ èyí.

Ìpàgọ́ yii se pàtàkì láti jẹ kí ayika tó tútù mọ́ wa lára látàrí ibi ìdíje AFCON ní Egypt tó máa tutù.
Ìpàgọ́ míràn yóò tún wà ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ keje oṣù kínní bákannáà tí àwọn ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù láti òkè òkun yóò ti darapọ̀ mọ́ wọn.

U20 AFCON yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kejì ọdún yìí. Àwọn tó pẹ̀lú Nàìjíríà ní ìsòrí ni : Orílẹ̀-èdè Senegal, Mozambique àti olùgbàlejò ìdíje -Egypt yóò kojú ara won ní ipele àkọ́kọ́.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

One response to “2023 U20 AFCON: Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles Yóò Ní Ìpàgọ́ Ìgbáradì Ní Òkè-òkun Ní Oṣù Kínní”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button