Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ Seyi Makinde fi ẹ̀mí ìmọ́ore hàn sí gbogbo àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ fún àǹfààní láti darí wọn gẹ̀gẹ̀ bí Gómìnà fún osù mẹ́tàlélógójì.
Gómìnà sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ ìsimi nínú ìkíni rẹ fún ọdún tuntun.O tẹ́síwájú wípé òhun ò fi àǹfààní náà fún ọdún mẹ́ta gbáko ṣeré.
Makinde ní àǹfààní yìí jẹ́ kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà mọ pé Ìjọba ohun dàgbà nípa ọ̀rọ̀ ajé ,ni ìrètí wípé òhun yóò tú wọlé gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ní oṣù kẹta ọdún 2023.
Gómìnà gbàdúrà wípé ọdún 2023 yóò jẹ ọdún tí ìjọba òhun o ṣe ohun pàtàkì má le gbàgbé ni ìpínlẹ̀ náà,o sí gbàdúrà fún gbogbo àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ fún àlàáfíà pípé.