Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣe ìkìlọ gidigidi fún àwọn ará ìlú Èkó láti dẹ́kun gbígbé epo rọ̀bì Pamọ́ sílé, ọja ati ilé iṣé gbogbo, èyí lẹ mú ìjàmbá iná wáyé.
Ìkìlọ yìí nṣe pẹ̀lú ìròyìn tí àwọn olùgbé Fastac town tí ìlú Èkó fi tó ìjọba létí nípa títa epo rọ̀bì ni òpópónà ni èyí tó ní ẹwu púpọ̀ fún àwọn ará ìlú.
Ọgá àgbà pátápátá fún àjọ tó mójútó ààbò ni ìpínlẹ̀ Èkó, Ọgbẹni Lanre Mojola, sọ wípé ìjàmbá nla lẹ ṣe yọ látàrí ayi bikita, pàápàjùlo nínú ọdún tuntun.
Ọgá àgbà pátápátá rọ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Èkó láti gbárùkù tí ìjọba lórí ìkìlọ̀ náà