Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe pápá ìṣeré MKO Abíọ́lá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 105

Ìjọba  Ìpínlẹ̀ Ògùn,gúsù-iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà, ti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe pápá ìṣeré káríayé MKO Abíọ́lá,ní olú-ìlú rẹ̀, Abẹ́òkúta láti pèsè ìtura fún àwọn olùwòran.

Ọ̀gá àgbà akọ̀wé fún ìròyin sí Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún,Kúnlé Somorin, sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan pé wọn yóò bo pápá ìṣeré tó lágbára láti gba ènìyàn ẹgbàárún náà tí yóò sì dùn mójú wò.

Somorin sọ pé àtúnṣe náà jẹ́ ara ìpinnu gómìnà láti gbé eré ìdárayá lárugẹ ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó sọ pé pápá ìdárayá náà ti wúlò fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù ìpínlẹ̀ àti ti aládàáni,pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Gateway àti ti káríayé Abíọ́lá Babes.

Leave A Reply

Your email address will not be published.