Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Senegal fẹ̀hónú wọn hàn lórí ìlòkulò owo Covid

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 139

Ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Senegal ti fi ẹ̀hónú wọn hàn ní Dakar,láti bèèrè ìgbésẹ̀ òfin lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìṣedéédé tí wọ́n rí nínú ìjábọ̀ ilé ẹjọ́ tó ń mójútó ìṣirò owó ,tí wọ́n fi ń gbógun ti ààrun Covid, àwọn oníròyìn pe àkíyèsí si.

Àwọn Ẹgbẹ́ àwùjọ ọmọ ìlú péjọ ní gbàgede orílẹ̀-èdè ní Dakar, tí wọ́n sì ń pariwo  “sí àwọn olè”! àti ‘ẹ kò ní jẹ bílíọ́nù wa’.

Àwọn ọlọ́pàá wà níbẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti mójútó ìwọ́de wọn, èyí tí alákóso fàṣẹ àti fọwọ́ sí,tí wọ́n sì ti bá ìjọba wí léraléra lórí ‘olè’ láìpẹ́.

Ní ààrin-Oṣù Kejìlá, ìjẹ́rìí ìwé ìṣirò owó láti ilé ẹjọ́ àwọn ajẹ́r̀íi ìwé ìṣirò owó ti Senegal lórí  ìdáhùn sí owó láti kojú ipa ààrùn Covid’ tí ó ju òjì lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rin bílíọ́nù cẹfa lọ,tí àwọn kan gbé sílẹ̀ àti ìpínlẹ̀ ní 2020 àti 2021,tí èyí sì ń tọ́ka sí ‘ìdààmú’,’ọ̀wọ́n’,tàbí ‘àìlárìí múdájú’ owó níná.

Ẹgbẹ́ Àwùjọ ará ìlú ń bèèrè fún ìkọ̀wé fipòsílẹ̀  gbogbo àwọn tí aje ìnákúuụná àti ìlòkulò owó náà sí mọ́ lórí.

Leave A Reply

Your email address will not be published.