Ìyàwó Gómìnà tí ìpínlẹ̀ Kwara àti Olùdásílẹ̀, Ajike People Support Centre, Ambassador Dr. Olufolake Abdulrazaq, tí ṣé àbẹwò sí ilé-iṣẹ́ àtúnṣe tí ìpínlẹ̀ Kwara, ní Amoyo, níbí tó tí fún wọ́n ní oúnjẹ àti àwọn nkán pàtàkì mìíràn.
Ìyá afin náà làkókò àbẹwò rẹ̀ ṣé àkíyèsí pé díẹ̀ nínú àwọn olùgbé ilé-iṣẹ́ àtúnṣe náà ní àwon italaya díẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ló sọ fún àwọn Alákóso ilé-iṣẹ́ náà látí ṣé ìtọ́sọ́nà àti ṣé ìtọjú wọ́n dáradára tí ìjọba Kwara kò sí ní f’ayé gbà ìbàjẹ́ èyí k’eyi.
Béè ló pé àwọn ilé-iṣẹ́, àrà ìlú àtí àwọn ẹgbẹ́ látí máà rántí àwọn ènìyàn wònyí ní igbagbogbo nínú àwọn ètò wọ́n.
Abdulrazaq ṣàfikún pé àwọn òun èlò oúnjẹ, àwọn òun èlò ilé, pàápàá jùlọ àwọn sikolashipu fún àwọn ọmọdé ní àwọn ilé ìtọ́jú wọ́nyi.
Abdulrazaq gbóríyìn fún Ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn Obìnrin ní Ìpínlẹ̀ Kwara àti Ilé Iṣẹ́ tó ń rí sí Ìdàgbàsókè àwùjọ fún akitiyan wọ́n láti rí i pé àwọn ilé náà ń ṣiṣẹ́ dáadáa.
Ṣáájú àkókò yìí, Kọmisana fún ọ̀rọ̀ àwọn Obìnrin ní ìpínlẹ̀ náà, Hajia Maryam Hassan gbóríyìn fún akitiyan Gómìnà bó ṣé ń ṣé àtìlẹ́yìn fún àwọn ilé ìtọjú tó wà ní ìpínlẹ̀ náà, o sí dúpẹ lọ́wọ́ Àyá Gómìnà fún bí wọ́n ṣé ń ṣé àtìlẹ́yìn fún ètò náà nígbà gbogbo.
Lekan Orenuga