Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìyànjú Ń lọ Lọ́wọ́ Látí Gbá Òṣìṣẹ́ Ilé Iṣẹ̀ Ọmọ Ogún Obínrin Tí Wọ́n Jigbe Sílẹ̀ – Ọmọ Ogún Nàìjíríà

1 104

Ilé iṣẹ́ àwọn ọmọ ogún Nàìjíríà tí fí tó gbogbo ènìyàn létí pé òṣìṣẹ́ Obìnrin tí wọ́n jigbe gbé lọjọ́ Àjé, ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù Kejìlá, ọdún 2022, Lieutenant PP Johnson, kò tíì gbá Ìtusílẹ̀ ṣùgbọ́n akitiyan wíwá sí ń lọ lọwọ́.

Obìnrín náà ní wọ́n jí gbé nígbà tó ń ṣabẹwo sí ìyá àgbà rẹ̀ ní Aku-Okigwe ní ìpínlẹ̀ Imo, ní kété tí ó parí ikẹkọ Cadet rẹ̀ àti bí wọ́n ṣé fún lóyè gẹ́gẹ́ bí Lieutenant sínú Ilé iṣẹ́ Ọmọ ogún Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde kàn tí Olùdarí Ibanisọrọ fún ilé ìṣe ọmọ ogún, Brigadier General Onyema Nwachukwu, fí síta, ó ní àwòrán ijinigbe rẹ̀ tí farahàn lórí ẹrọ ayélujára àwùjọ níbí tí àwọn ajinigbe rẹ̀ tí sọ pé jijigbe rẹ̀ jẹ́ ní ìlànà pẹlú ìjà fún Biafra tó lòdì sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nítorí náà, Ẹgbẹ́ ọmọ ogún Nàìjíríà sọ di mímọ̀ fún àwọn tí wọ́n ṣì ń ṣiyèméjì nípa ipò òtítọ́, pé IPOB/ESN jẹ́ apanilaya, tí wọ́n ń farahàn gẹ́gẹ́ bí jagunjagun òmìnira, tí wọn kò sì yẹ kí wọ́n ní àtìlẹ́yìn ẹnikẹ́ni ní pàtàkì àwọn ènìyàn réré ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ ọmọ ogún tún ṣàlàyé pé Arábìnrin náà kò tí rí Ìtusílẹ̀ atipe kìí ṣé ilé iṣẹ́ ọmọ ogún ló ń ṣé ìgbìyànjú náà, o sí sọ́ pé òun mọ́ rírí àwọn àrà ìlú lórí ipò tí arábìnrin náà wà.

Ilé-iṣẹ́ ọmọ ogún Nàìjíríà fí dá àwọn aráàlú lójú pé àwọn kò níí fí òhun kàn sílẹ̀ láì f’ọwọ́ bà lóri akitiyan láti gbà ọgagun náà sílẹ̀, kí wọ́n sì fí ìyà jẹ́ àwọn aṣebi náà. Wọ́n sì rawọ ẹbẹ sí gbogbo aráàlú látí pèsè àlàyé tó dájú tó lè mú kí arábìnrin náà gbà ìtusílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn asebi náà.

Lekan Orenuga

1 Comment
  1. […] Tún kà nípa: Ìgbìyànjú Ń lọ Lọ́wọ́ Látí Gbá Òṣìṣẹ́ Ilé Iṣẹ̀ Ọmọ Ogún Obínrin… […]

Leave A Reply

Your email address will not be published.