Gẹ́gẹ́ bí ọnà látí ró àwọn Ilé-ìwé àti àwọn ọmọ akẹkọ lágbára ní ilẹ̀ Áfíríkà. L’ọ́ṣẹ́ yìí, CAF tí ṣé ìfilọ́lẹ̀ àwọn Ilé-ìwé ní ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n pé ní “Africa School Football Championship” tí ń ṣé ìwúrí fún àwọn ọdọ.
Ìdíje Bọ́ọ̀lù Àwọn ilé-ìwé Áfíríkà: ètò àwọn ilé-ìwé yìí tún jẹ́ òun tí àjọ CAF ń náwó lé lórí nitori àwọn ọdọ tí Áfíríkà.
– Ìdíje àpẹẹrẹ ife-ẹ̀yẹ tí ṣii Sílẹ̀ ní báyìí
– Àwọn ọmọ ilẹ Áfíríkà tó ń kẹkọ Àwòrán àtí Àpẹẹrẹ (Art and Design) ní wọ́n tí rọ̀ látí kópa, wọ́n sì lè kópa nínú ìlànà ìdíje náà
– Èyí jẹ́ ìpolongo ànfààní mìíràn fún CAF láti súnmọ́ àwọn àrà ìlú àti àgbègbè
– Ìdíje náà yóò wáyé látí Ọjọ keje, Oṣù Kẹ́rin sí Ọjọ́ kẹsán, Ọdún 2023.
Olubori níbi ìdíje náà ní yóò gbé ife-ẹ̀yẹ tí Continental Phase of the African Schools Football Championship náà.
Àkòrí ìdíje náà ní: “Bọ́ọ̀lù Àwọn ilé-ìwé Áfíríkà.”
Sarah Mukuna Olùdarí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ CAF sọ pé, “A fẹ́ kí ìdíje náà jẹ́ aṣojú àtí òun ìwúrí fún àwọn ọjẹ̀ wẹ́wẹ́ ilẹ̀ Áfíríkà. Inú wa sí dùn fún iṣẹ́ àkànṣe yìí.”
Lekan Orenuga