Alàgbà ọlọ́lájùlọ Owen Nwoko ti sọ pàtàkì kérésìmesì, ó sì sàlàyé pé bíbí Jesu jẹ́ àfihàn àánú Ọlọ́run lórí ọmọ ènìyàn.
Ó sọ wípé àánú Jésù kárí gbogbo ayé láìfi ti ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn se.
Alàgbà náà wá rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù fún ìtẹríba àti ìfarajì láti le è nípa nínú ìrètí ayọ̀ tí Jesu múwá. Ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, ọdún ayọ̀ àti ìdùnnú ni ọdún 2023 yóò jẹ́.