Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Kwara Gba Àwọn Olùdìbò Níyànjú Láti Gba Káàdì Ìdìbò

0 148

Ìjọba ìpínlẹ̀ kwara ti pe àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà láti ri dájú pé wọ́n gba káàdì ìdìbò wọn, permanent voters card, pvc síwájú ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2023.

 

Alákòsóo ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Abubakar Saddiq Buhari ni ó pe ìpè náà láti fi mọ rírì ipa olùdìbò nínú ètò ìdìbò. Ó se àkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ ni kò gba káàdì ìdìbò wọn.

 

Buhari wá gba àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ kwara níyànjú láti dìbò fún olùdúje tí ó dára àtipé kí wọ́n jìnà sí ìwà jàǹdùkú àti jàgídíjàgan síwájú àti lẹ́yìn ìdìbò.

Leave A Reply

Your email address will not be published.