Ẹlẹ́sẹ̀ẹ́ kù bí òjò ọmọ Nàìjíríà, Anthony Joshua sọ wípé òun ti gbáradì fún ìtẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí yóò gbégbá orókè jùlọ nínú eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ jíjà.
Joshua, ẹni tí ó fi iga gbága pẹ̀lú Olekandr Usyk nínú osù kẹjọ (August) tí ó sì fìdí rẹmi láti gba àmì ẹ̀yẹ WBA, WBO àti IBO.
Akitiyan ń tẹ̀síwájú láti jẹ́ kí Joshua kojú Tyso Furry fún àmì ẹ̀yẹ WBA, sùgbọ́n àfẹnukò kò ì tíì wáyé lórí rẹ̀. Anthony Joshua sọ wípé òun wà ní ìgbáradì ní gbogbo ìgbà, àtipé yóò tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ rẹ̀.