Take a fresh look at your lifestyle.

A Ti Se Ìfiléde Ìdùwò Àwọn Dúkìá Tí Ìjọba Gbẹ́sẹ̀ Lé- Àjọ Tí Ó Ń Gbógun Ti Ìwà Àjebánu Fi Ọ̀rọ̀ Léde

0 120

Àjọ tí ó ń gbógun ti ṣíse owó ìlú kúmọ-kùmọ, The Economic and Financial Crime Commission sọ wípé, gbogbo ètò ti parí láti lu àwọn ohun ìní tí ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé ní gbàǹjò.

 

Agbenusọ àjọ náà, ọ̀gbẹ́ni Wilson Uwujen ni ó sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà wípé ànfààní wà fún gbogbo ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ láti rà nínú àwọn dúkìá náà títí aago méjìlá ọ̀sán ọjọ́ ajé (Monday) ọjọ́ kẹẹ̀sán osù kíní ( 9th January, 2023) láti fi ìdùwò wọn léde.

 

Ọ̀gbẹ́ni Uwujen tèsíwájú pé, ilé ìgbé mérìnlélógún (24) wà ní Banana Island ní ìlú Èkó, mọ́kànlélógún (21) wà ní Thombum, Yaba nígbà tí mẹ́rìndílógún (16) mínràn sì wà ní ìlú Port Harcourt. Ó sàfikún pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé àti ilẹ̀ ni ó tún wà ní ìpínlẹ̀ bíi Anambra, Ebonyi, Gombe,Kaduna, Delta,Edo, Osun, Oyo àti ìlú Abuja.

 

Ó sìsọ lójú eégún ọ̀rọ̀ náà pé, àlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́ wà lójú ẹ̀rọ ayélujára àjọ EFCC, www.efcc.gov.ng

Leave A Reply

Your email address will not be published.