Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti Orílẹ̀-èdè Gambia ti gbá àwọn ológun méjì mú tí wọ́n funra sí wípé wọ́n lọ́wọ́ nínú Ìdìtẹ̀gbàjọba ààrẹ
Adama Barrow lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Àwọn méjì náà tí wọ́n kò tí dárúkọ wọn ní wón gbámú ní ọjọ́ ajé.
Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù yìí, ìjọba kéde rẹ̀ pé àwọn mú wọn látàrí Ìdìtẹ̀gbàjọba.
Àjọ Economic Community of West African States (Ecowas), ti bù ẹnu àtẹ́ lu Iditegbajoba náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san