Ilé ẹjọ́ tó kalẹ̀ sí ìlú Minsk ti sọ eléré-ìdárayá àná, awedò, Aliaksandra Herasimenia àti ajajangbara olóṣèlú Alexander Opeykin sì ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá látàrí ìpè tí wọ́n pe láti gbé òté àti ìgbésẹ̀ lé ètò ààbò ìjọba àpapọ Orílẹ̀-èdè Belarus.
Belarus ni àwon ọ̀pọ̀ orílè-èdè àti United Nations kò fi ojú rere wò látàrí ìhà burúkú tí wọ́n kọ sí àwọn òṣèlú alátakò, àwọn ènìyàn àti àwọn oníròyìn.
Bí Ẹ́mbáássì ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní ìlú Belarus se sọ, ọgọ́fà ààbọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú ló wà ní ìlú Belarus.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san