Ìjọba orílẹ̀-èdè Italy ti ṣèlérí àtìlẹ́yìn fún Kyiv láti ri pé àlàáfíà nìkan soso jọba, èyí wáyé lẹ́yìn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láàrín ààrẹ Giorgia Meloni àti ààrẹ Volodymyr Zelenskyy.
Nínú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti tweet, Zelenskyy dúpẹ́ lọ́wọ́ Meloni fún àtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ fún wọn, àti wípé orílẹ̀-èdè Italy ń gbìyànjú àti pèsè nkàn ìjà ti ojú òfurufú fún Kyiv.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san