Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Djokovic Balẹ̀ Gùdẹ̀ Sí Australia Látàrí Ìdíje

0 98

 

Novak Djokovic ti gúnlẹ̀ ṣí ìlú Australia ní ǹkan bí ọdún kan géérégé tí wọ́n dáa padà kúrò ní ìlú náà.ìròyìn ro pé o dé fún ìdíje ẹlẹ́ni mẹ́wàá ti yóò bẹ̀rẹ̀ ní osù tó ń bọ̀ tí wọn n pè ní “Australian Open”.

 

Ó gúnlè sí Adelaide fún ìdíje ní Adelaide International ní ọjọ́ Àìkú, ìròyìn ròo.

 

Ẹni Ọdún márùn ún dín lógójì náà ni wón dá padà síbi tó ti ń bọ̀ ní ìgbàtí eré ku ọ̀la ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni Melbourne ní kété tí ó gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà láì gba abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19.

 

Ní oṣù kọkànlá, ìjọba Australia fún ará Serbia náà ni ìwé ìrìǹnà látí lọ fún ìdíje tó fẹ́ lọ lẹ́yìn tí wón ti se àyẹ̀wò gbogbo tó yẹ, wọ́n ṣì ti yí ìpinnu wọn àkọ́kọ́ padà.

 

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbé òté lórí ìwé ìrìn-àjò ògbẹ́ni Djokovic ní oṣù kínní ọdún yìí, gbogbo òfin tó ṣo mọ́ COVID nípa àìlewọ ìlú kan sí òmíràn àti àdánimọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára gbígbà pátápátá ni wón ti mú kúrò.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.