Ààrẹ Buhari ti bù ẹnu àtẹ lu ìlùfin àti àìmọ́gbọ́ndání Ìsekúpa, amòfin ti Nigerian Bar Association NBA, Omobólánlé Raheem, ní ọjọ́ kérésìmesì láti ọwọ́ olópàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́.
Ààrẹ sọ wípé, enu ya oun, òun sì ṣọ̀fọ̀ ẹni tí olópàá pa náà, o pàṣẹ ki ìjọba àwọn olopaa se ìdájọ tó yẹ fún ẹni ibi náà ni kíámọ́sá ti won ti gbe ju sí atimole bayii.
“Ní àkókò ìbànújẹ́ yìí, gbogbo omyo orílẹ̀-èdè yìí wà nínú ọ̀fọ̀ àti ìdúrótì àwọn ẹbí olóògbé àti NBA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ òdodo yóò di ṣíse” ààrẹ sọ èyí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san