Ikọ̀ agbábọ̀ọ̀lù Argentina Gbo omi Ewúro Sójú Ikọ̀ agbábọ̀ọ̀lù France Nínú Ìdíje Àsekágbá Ife Àgbáyé
Ikọ̀ ti Argentina tí Lionel Messi jẹ́ Balógun wọn gbo ewúro sí ojú tí alátakò wọn- France ni àkókò wòmí ki n gba sí ọ – Penalty nínú àsekágbá ìdíje ife àgbáyé ti ó tẹnu bepo lánàá.
Balógun ẹgbẹ́ agbábọ́ölù Argentina, Lionel Messi gbé ikọ̀ rẹ̀ dé èbúté ògo lálàá ní ìgbà tí wọn n gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú orílẹ̀-èdè France lórí pápá pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí méjì (4-2) léyìn ìgbà ti wọ́n ti kọkọ gbá bọ́ọ̀lù ọ̀min ayò mẹ́ta sí mẹ́ta (3-3) lẹ́yìn ọgọ́fà ìṣẹ́jú bótilẹ̀jẹ́pé ẹlẹ́sẹ̀ ayò ọmọ France gbá bọ́ọ̀lù onibẹta wọlé Argentina síbẹ ẹ̀pa kò bóró mọ́ ní pápá ìseré Lusail ni Al Daayen, orílẹ̀-èdè Qatar.
Ní ìgbà tí wọ́n ńgbá bọ́ọ̀lù wò mí kí n gba sí ọ (Penalty), Mbappe ti Orílẹ̀-èdè France ló kọ́kọ́ gbá ayò àkókò wọlé tí Messi ti Argentina náà sí mi àwọ̀n tirẹ̀.
Kinsgley Coman àti Aurelien Tchouameni ti orílẹ̀-èdè France sọ bọ́ọ̀lù tiwọn nù tí agbábọ́ọ̀lù mẹ́ta tí ó kù ti Argentina sì gbá tiwọn wọlé, Montiel ti orílẹ̀-èdè Argentina ló gbá eléyìí tó gbèyìn wọlé ti wọ́n sì gba ife àgbáyé ti ọdún 2022.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san